IGI OJIJI ( THE SHADOW TREE)
IGI ÒJÌJI Ní igbo dídí kan tí ó wà lẹ́yìn abúlé Ilé-íyá, igi ńlá kan wà tí gbogbo ará ìlú ń pè ní Igi Òjìji. Igi yìí yàtọ̀ sí gbogbo igi yòókù; kò ní ewé kankan lára, sùgbọ́n òjìji rẹ̀ máa ń gùn, ó sì máa ń yí padà láìsí oòrùn kankan lókè. Àwọn àgbàgbà sọ pé igi náà jẹ́ ẹnu-bodè láàárín ayé àwọn alàyè àti ilẹ̀ àwọn òkú. Kò sí ẹni kankan tí ó gbọdọ̀ sún mọ́ ọn nígbà tí oòrùn bá ti wọ̀. Àremu jẹ́ ọmọkunrin tí ó lágbára, tí kò sì bẹ̀rù ohunkóhun. Ọmọkunrin ọlọ́kàn-líle ni. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, nítorí àìsàn gbígbóná tí ó ṣe ìyá rẹ̀ tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀, Àrẹ́mu pinnu láti lọ sí abẹ́ Igi Òjìji. Wọ́n ní egbòogi kan ṣoṣo tí ó lè gba ìyá rẹ̀ là wà lábẹ́ igi náà, ṣùgbọ́n ó ní láti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn ọmọ-onílẹ̀ tí ń bẹ lábẹ́ igi náà. Bí alẹ́ ṣe lẹ́ ni , Àrẹ́mu mú fìtílà rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn lọ síbẹ̀. Bí ó ṣe ń sún mọ́ igi náà, afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ lójijì, àwọn ẹyẹ alẹ́ sì ń kígbe. Òjìji igi náà bẹ̀rẹ̀ sí ní tàn sápá ibi tí ó wà. Nígbà tí ó dé abẹ́ igi náà, ó rí eg...
