IGI OJIJI ( THE SHADOW TREE)
IGI ÒJÌJI
Ní igbo dídí kan tí ó wà lẹ́yìn abúlé Ilé-íyá, igi ńlá kan wà tí gbogbo ará ìlú ń pè ní Igi Òjìji. Igi yìí yàtọ̀ sí gbogbo igi yòókù; kò ní ewé kankan lára, sùgbọ́n òjìji rẹ̀ máa ń gùn, ó sì máa ń yí padà láìsí oòrùn kankan lókè. Àwọn àgbàgbà sọ pé igi náà jẹ́ ẹnu-bodè láàárín ayé àwọn alàyè àti ilẹ̀ àwọn òkú. Kò sí ẹni kankan tí ó gbọdọ̀ sún mọ́ ọn nígbà tí oòrùn bá ti wọ̀.
Àremu jẹ́ ọmọkunrin tí ó lágbára, tí kò sì bẹ̀rù ohunkóhun. Ọmọkunrin ọlọ́kàn-líle ni. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, nítorí àìsàn gbígbóná tí ó ṣe ìyá rẹ̀ tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀, Àrẹ́mu pinnu láti lọ sí abẹ́ Igi Òjìji. Wọ́n ní egbòogi kan ṣoṣo tí ó lè gba ìyá rẹ̀ là wà lábẹ́ igi náà, ṣùgbọ́n ó ní láti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn ọmọ-onílẹ̀ tí ń bẹ lábẹ́ igi náà.
Bí alẹ́ ṣe lẹ́ ni , Àrẹ́mu mú fìtílà rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn lọ síbẹ̀. Bí ó ṣe ń sún mọ́ igi náà, afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ lójijì, àwọn ẹyẹ alẹ́ sì ń kígbe. Òjìji igi náà bẹ̀rẹ̀ sí ní tàn sápá ibi tí ó wà.
Nígbà tí ó dé abẹ́ igi náà, ó rí egbòogi náà tí ó ń tàn fòò. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe fẹ́ mú un, òjìji rẹ̀ (ti Àdrẹ́mu) yà kúrò lára rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bá a sọ̀rọ̀!
"Àrẹ́mu," òjìji náà sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ bí ohùn afẹ́fẹ́. "Tí o bá fẹ́ gba egbòogi yìí láti gba ìyá rẹ là, o gbọdọ̀ fi nǹkan kan sílẹ̀ láti dípò rẹ̀. Ohun tí o bá sì fi sílẹ̀ kò ní padà sọ́wọ́ rẹ mọ́."
Àrẹ́mu kò fọ̀ lẹ́nu. Ó mọ̀ pé láìsí ìyá rẹ̀, ayé òun kò ní itumon kan kan. "Mú òjìji mi," Àrẹ́mu sọ pẹ̀lú igbóyà. "Mú òjìji mi lọ, kí o sì fún mi ní egbòogi náà."
Òjìji náà rẹ́rìn-ín músẹ́. Gbogbo igbo mì tìtì. Ní iseju kán, òjìji Àrẹ́mu pòórá mọ́ Igi Òjìji lára. Àrẹ́mu rí egbòogi náà mú, ó sì sáré padà sílé.
Ìyá rẹ̀ rí ìwòsàn gbà lẹ́yìn tí ó lo egbòogi náà. Ṣùgbọ́n láti ọjọ́ náà lọ, tí oòrùn bá ti yọ tàbí tí fìtílà bá tàn, gbogbo ènìyàn máa ń ní òjìji lẹ́yìn wọn, àyàfi Àrẹ́mu. Ó di ọmọkunrin tí kò ní òjìji, ó sì di alágbàṣe fún Igi Òjìji títí láé.
Comments
Post a Comment